Header Ads

Ona Agbelebu (The Stations of the Cross)

ADURA IBERE
Wo! Mo dobale ni ese Re, Jesu rere mi, lati se asaro ijiya mimo ati iku Re, ati lati jere opolopo indulgensi ti ona agbelebu. A! ki nba le ni aanu iya Re mimo ati itara opolopo awon Kristiani ti nti ipa ona yi jere pupo ti won si nyo emi pupo kuro ninu Pulgatori. Se mi ni ore ikorira ese ati ifarawe iwa rere Re, kin le ye fun eje iyebiye ti O ta sile fun mi, lati ri ade egun lori Re ati lati gbo gbogbo oro Re.
ORIN: Ni omije, ni ibanuje
Iya duro lese igi
Ni ibi t'omo re njiya.

            IBUSO KINI.
              A DA JESU LEBI IKU
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Ha Pilatu, onidajo buburu, ko i pe tobe ti o ti wipe iwo ko ri ebi kan lowo Jesu ati pe Oun je alailese, nisisinyi Iwo da A lebi iku ti o ti eniyan loju ti o si buru julo. Talo nani iwewo ati wiwi re pe, iwo ko lowo ninu iku Olododo yi, bi iwo ti fii fun awon ti o buru ju ninu awon ota Re, sugbon Jesu rere mi, kini yoo da fun mi lati da ara mi lare asehan, bi o ba sepe nipa didese, emi tun fenu si idajo buburu ti Pilatu da O.
Emi ki yoo tun se eyi mo, Oluwa, mo bee O, nipa ina ika ti o di ogbe si O lara, ati orisirisi oro egan ti o ti gba nitori mi, lati ma tun je ki nse be mo.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Lehin imi edun topo,
  Lehin ainitunnu rara,
Ida oro gun un lokan.

IBUSO KEJI
A MU JESU RU AGBELEBU RE
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Wo, won gbe ohun ijiya ti Jesu fun U. Nje yoo ha le ru bi? O wuwo pupo awon agbara re si ti buru pupo. O ni lati gbe laarin awon ole meji ni osan gangan ati loju opolopo eniyan ti pegan Re. Oun a le salo bi? Ni igba ti won fe fi Jesu joba, O sapamo; sugbon nisisiyi ti iwosi ati iya oniruru nreti Re, Oba ogo ko salo. Lati odun metalelogbon ni o ti nreti ojo yii, nitori naa ni O gba ti O fa mora, ti O siru agbelebu Re pelu aanu ailopin nitori ife temi tire.
Kristiani, nje iwo gba agbelebu ti Olorun fun o bakanna bi?
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Olubukun Iya Jesu
Ti ni inu to baje to
Fun oniruru iya.

IBUSO KETA
JESU SUBU LEKINNI
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Bi o ti wu ki igboya Re po to, Jesu nipa oro ti O ti je ko le kara duro laisubu labe eru Re buburu yi; ojuju melomelo ni igun agbelebu nda si ejika Re ti o n ro O. Won je ki idi igi ti o gun ti o si wuwo yi ma kan ile. Ijiya wo ni idi yi ti ngbun okuta fun Jesu. Mo ri agbara eje ti o nsan lati inu ogbe Re kakiri gbogbo ode, Oun ko tun leru mo, O si subu nipa irora ati iwuwo igi naa.
Kristiani, woo bi ese re ti mu Jesu jiya to.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Ko si simi, kosalafia,
Eniyan woo kii yo sokun
T'o nri Omo n'irora.

IBUSO KERIN
           JESU PADE IYA RE.
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Irora nla wo ni yoo je fun Iya kan lati rii ki a da omo re lebi iku, bi o tile je pe Oun ni o buru ju ninu gbogbo eniyan ati pe, ki ounsi ti ba oun ninu je pupo. Maria di eniti o nwo omo re ti ko jebi ti o je mimo paapaa, Olufe ati Olorun ti  O di eniyan. Pelupelu, a da Maria lebi lati ripe, leyin ilukilu ti won lu Jesu, ti o so gbogbo ara Re di ojuju tan, won tu mu lo pa ni ipa itiju. Irora nla wo ni eyi fun Wundia Mimo. Sugbon, o fi Omo re fun Olorun Baba, o si fe lati padanu Re ju lati da ise igbala wa duro lo.
Nje, yoo dara be, iwo elese, lati so oro iru omo bayi, ati irora iru Iya bayi d'otun nipa ese re bi.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Eniyan wo ki yoo sokun
Ti o ba ri Iya Kristi
Ni owo iponju yi?

IBUSO KARUN
SIMEONI ARA SIRENI RAN JESU LOWO LATI RU AGBELEBU RE
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Bawo ni ayo Simeoni, eni ti a ro lati ba Jesu ru agbelebu re, ti po to Emi iba le gba ipo re; ki nsi le tu o ninu Jesu rere mi, nipa biba O ru eru ti o wuwo yi. Beeni, omo mi, iwo le tu mi ninu; gba agbelebu ti a fun o pelu ayo, alaafia yoo si po fun o ju ara Sireni lo. Iwo yoo si ti ipa bee ran mi lowo lati gbe agbelebu mi. A! bawo ni iba ti dun to bi o ba se pe iwo mo bi inira ati wahala aye yii ti ni iye lori to. Sugbon bi o ti je pe iwo ko ka iye ailopin ti awon iponju ati inira ti aye yii maa nfun ni si, iwo a maa gba won pelu iberu, iwo a maa kun fun ejo wiwi, iwo a si maa kun simi. Looto ni Oluwa, beni mo se titi di akoko yi; sugbon mo fe wi pelu Augustini Mimo pe: lati isisiyi lo Olorun mi, mo fe ki a sun mi ni ina, ki a si pon mo loju bi iwo yoo ba da mi si ni aye ti nbo.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Ta bi ta ni ki yoo saanu
Fun iya to dara to bee
T'o si ba omo pin ya?

IBUSO KEFA
VERONIKA RERE NU OJU JESU
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
E wo bi iwa rere Veronika ti yato si tiwa to. Nigba ti o ri awon panipani ti o yi Oluwa ka lati lo pa A, ti oju re si kun fun ito ati eje. Obinrin alaiberu yi re awon eniyan koja, o si nu Jesu loju. Sugbon, ohun kekere kan, egan, eru lasan tabi ero ohun ti araye yoo wi to lati deruba awa Kristiani; o to lati je ki a ko ona agbelebu, Ara Oluwa ati gbogbo ise isin sile. Sugbon, e wo iyato ti nbe ninu igbeyin won. Veronika di eni mimo, Jesu ya aworan Re sinu gele ti o fi nu U loju; sugbon awon ti ko sise won yoo di eni itiju ati eru titi lo.
A! Oluwa, nigba wo ni iwo yoo gba mi kuro ninu iberu eniyan ati ihuwa buburu yi?
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Ori pe Jesu nwahala
Nkerora ni ona gbogbo
Fun ese ara tire.

IBUSO KEJE
JESU SUBU LEEKEJI
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Bi o tile je pe Simeoni ara Sireni nba A gbe agbelebu Re, Jesu si tun subu leekeji. Oro ibaje ati oro odi melomelo ni awon apaniyan buburu wonyin ko wi si lara tan! Pelu iwa ika ni won ko si tun lu U bi O ti subu! Sibesibe, Jesu ko wijo. Bi o ba se ami kan ni, se ni ile iba lanu lese kanna, ti iba si mi awon eniyan buburu yi laaye sinu orun apadi.
Sugbon kaka ki O se eyi, Oun fe jiya si nitori ife tiwa. E wo bi inu rere Oluwa ti tobi to! Emi ko mo iya kan je nitori tire. Nipa ibaje kekere kan tabi oro iwosi, emi a bere si bu ebu ati lati ma soro imunidese. Bi o si ti je pe laisi ina ati iro owu, alagbede ko le se ise rere kan, bee ge ni, laisi agbelebu ati iyonu, emi ko le wun ade mi ti orun.
Be lori Jesu, ati lati isisiyi lo, pelu iranlowo oore-ofe Re, emi yoo gba gbogbo iya ti O fi fun mi pelu ayo, bi o ti wu ki o lodi si ife ara mi to.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.

ORIN: O nwo omo re olufe
To ndaku lo nibanuje
T'oku tan b'eni egbe!

IBUSO KEJO
JESU TU AWON OBINRIN JERUSALEMU NINU
Oludari: Awa forbale fun O, Jesu, a si yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ti fir a araye pada
E wo bi iwa rere okan Jesu tipo to! O gbagbe ijiya Re, O si nkaanu awon obinrin ti won nsokun tele E leyin, O si wipe, eyin omobinrin Jerusalemu, e ma sokun fun mi, sugbon, e sokun fun ara yin ati fun awon omo yin; Nitori, bi  won  ba se nkan wonyi lara igi tutu melomelo ni a o se lara igi gbigbe. Eyi  jasi  pe, bi a ba se alaise bayi, bawo ni a o ti se elese? Beni elese ni o je eni kan soso ti ko sokun; o mo wipe oun wa ninu iwa ese nla, ati pe bi oun ba ku sinu iwa yi, oun yo jona ninu ina orun-apadi; o si nfi eyi se erin rin, o nsere, o si nyo pesepese leti bebe ogbun buburu yi;
A! wo o bi aifoya ati aini itiju yii titobi to.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: A! iya mi, ori ife
  Nba ti fe ba o kaanu po
  Nba ti feda omije

IBUSO KESAN
JESU SUBU LETA
Oludari: Awa forbale fun O, Jesu, a si yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ti fir a araye pada
 Beni, Jesu subu l’eketa labe agbelebu Re. Ibaje, ilu ati iwa ika l’otun l’osin situn wa lati owo awon juu; otun ibanuje ati irora, otun inu rere ati aanu ti odo Oluwa wa. O dabi enipe orun apadi tu ibinu re ka le Oun lori. Kini Jesu yoo se? Nje ki yoo pari ise Re? Nje, yo se bi awa ti o je pe nipa ilodi kekere kan, a o fi ona iwa rere sile bi? Agbedo! Agbedo! Won le wi fun pe: Bi iwo ba je omo Olorun,  sokale kuro lori agbelebu, ati nipataki nitori Oun je omo Olorun, Oun a si duro sibe titi di amideku Re.
Oluwa, bi o ti wu ki o ri, pelu iranlowo oore-ofe Re,  mo feran Re titi de oju iku.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Nba tife ki inu mi kun
Fun ife mimo si Olorun
Kin le wu o n’idaju.

IBUSO KEWA
WON BO JESU L’ASO WON SI FUN UN L’ORORO MU

Oludari: Awa forbale fun O, Jesu, a si yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ti fir a araye pada
Oba ogo, Eniti nfi ewe fun igi, ti nfi ododo fun oke, ti nfi imole fun sanma, won bo aso Re l’osan gangan ati l’oju opolopo eniyan ti nkegan Re, ojuti ati iya wo ni eyi fun Oluwa. Bi aso ti le mo ara Re, ti eje sigbe mo oju ogbe, eran sin moo, o si tun so ogbe ti o ju egbeedogbon wonyi, ti awon eni buburu yi da si ara Re d’otun. Bawo ni iwa aimo ati ifekufe ti o so mi elebi ti mu Jesu jiya to.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Iya mimo emi nbe o,
Fun ogbe ti Jesu Kristi
Ni inu mi titi lo

IBUSO KOKANLA
A KAN JESU MO AGBELEBU
Oludari: Awa forbale fun O, Jesu, a si yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ti fir a araye pada
Wo  bo Jesus l’aso, won si fun Un ni ororo ati oti kikan mu. Nisisiyi, won pase fun Un pe ki O dubule lori agbelebu.
Nje, yoo gbo tiwon bi? Laisi aniani, iwo tina owo re si ohun ti a palase fun O. Jesu ti na owo Re pelu, ki won ba le kan ni iso ti o wuwo.
Ero yi mu o gbon riri fun iberu! Beni, Jesu je alailese, iwo si jebi iyanainepkun. Ro ohun ti o nse lowo. Iro owu nba okan Maria je; iso ngun eran ara Jesu; o nja isan Re; o nfo egunegun Re; agbara eje si san l’ara Jesu.  A! wo bi o ti mu Jesu jiya to, iru awon ohun ti araye maa n pe ni ohun lasan, ti itiju lasan si maa nje ki won pamo ninu ijewo ese won lodo Sasedoti!
 Jesu rere mi, ma je ki ntun da owo Re lu mo nipa awon ise aimo, tabi ki ntun kan iso mo ese Re nipa ririn ni ona buburu.
  BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: Pin fun mi ninu ijiya
Ti omo re Oluwa wa
Eni t’ora wa pada.

IBUSO KEJILA
JESU KU LORI AGBELEBU
Won gbe agbelebu soke, won jin lojiji sinu iho ti won ti gbe s’ori oke. Idamu ati wahala wo, ni ilo aye yi se l’ara Olugbala. Jesu de inu ipohaha iku. Elese, wo Baba re, Eleda ati Olorun Re ni; nitori re ni o jiya iku. Wi fun mi, nje irora kan wa ti o to tire? Nisisiyi, bi o gbe oju s’oke orun, Oun ko ri Angeli lopolopo lati sokale wa sin I, bi ti inu iju. Idajo Olorun sin gbogbo agbara re le E lori. Bi o ba wo aye, ko gbo nkan miran  bikose, igbagbe ati aimore, titi de ibi pe ibanuje ti iya mu irora omo po sii. A! nigba melo melo ni awa nduro tifetife ninu iwa egbe?
Jesu rere mi, ma je ntun je okan ninu awon alaimo yi ati ki emi ma tun se se mo si Olorun ti O dara tobe.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.

ORIN: Mu ki nba O kaanu pupo
Ki nsaajo ijiya Kristi
Ni’jo aye mi gbogbo

IBUSO KETALA
A GBE OKU JESU SOKALE LORI AGBELEBU A SI FIFUN IYA RE.
Iya onirora, je kin sunmo Omo re, ki nsi bo Olugbala mi. Wo bi O ti a l’oku si aya re. Ma a boo mo mi, wo bi awo Re ti yipada; wo bi egun ti gun U lori; wo bi a ti pa aworan Re kale. Oju Re, ti o je ayo orun rere ti wonu; okun ahon Re, ti o ti so oro rere ti iye ainipekun kun fun oro; awon ese Re, ti ma nwa awon elese ka laisimi ti dalu fun iso; awon owo Re, ti o tin se ise nlala dalu; Wo o, O ti ku!
Nisisiyi, ro idajo Olorun ati ikorira ti Oluwa ni fun ese; ki o dupe lowo Jesu, ki o si bukun fun ife ailopin Re.
  BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
Oludari: Saanu fun wa, Oluwa.
Idahun: Saanu fun wa.
Oludari: Nipa aanu Olorun ki emi awon olododo ti o ti se alaisi simi lalafia.
Idahun: Amin.
ORIN: L'ese agbelebu Jesu
Mo fe lati ba O s'egbe
Lati ba O kerora.

IBUSO KERINLA
A SIN JESU SINU ISA OKU
Oludari: Awa foribale fun O, Jesu, a sin yin O logo
Idahun: Nitori nipa agbelebu mimo Re lo ra araye pada.
Ki won to se isa oku ti o gba isura ti orun ati ti aye,e tun wo Olufe ati Olugbala yin sii l'awodeku. A! Nisisiyi ni mo to ri ohun ti won npe ni asan ati ireju aye yi je. Kini won ti so Olorun ati Oluwa mi da? Ati nipa iri ogbe wonyi, iwo okan mi a tun le ma dese si Olorun to dara to be bi?
Oorun, Osupa ati awon irawo nmi nitori iku Jesu; afi emi nikan soso l'osaimo. Emi yoo ha tun pa A nipa ese mi bi? Agbedo, ki nku, ki nku nigba egberun, terun ju ki tun se O lo.
BABA WA TI NBE LORUN..........
MO KI O MARIA..........................
OGO NI FUN BABA.....................
ORIN: Nigba ti ara mi ba ku
Mu ki okan mi k'o wa je
Ogo ti orun rere

ADURA NIWAJU ALTARI
Asiwaju: Wundia onibanuje gbadura fun wa
Ijo: Ki awa ba le ye fun ileri Kristi
Asiwaju: Oluwa, iwo ti se ami si ara omo odo Re, Fransisku mimo
Ijo: Pelu ami irapada wa
Asiwaju: E je ki a gbadura fun Papa wa.................Ki Oluwa ki o pa mo, ki o fun ni emi gigun ati alaafia lori ile aye, ki o ma si se fi le awon ota re lowo.
Asiwaju: E je ki a gbadura fun awon olododo oloogbe
Ijo: Oluwa, fun won ni isimi ainipekun, ki O si fi imole ainipekun han fun won.

E JE KI A GBADURA
Olorun fiyesi I, awa nbebe lodo Re lati fi oju annu wo idile yi fun eyi ti Jesu ko se iye meji lati fi ara Re le awon olupani Re lowo,ati lati je oro agbelebu.
Jesu, omo Olorun alaye, Iwo eniti a kan mo agbelebu ni agogo meta loju ale fun irapada araye, ti O si ta eje Re oniyebiye sile fun imukuro ese wa, awa nfi irele okan bebe lodo Re pe, lehin iku wa, ki O gba wa sinu ibugbe ogo ainipekun.
Awa nbebe lodo Re, Oluwa Jesu, je ki a le wu Maria Wundia mimo, iya Re, okan eniti a fi oko irora gun ni akoko ijiya Re, lati sipe fun wa nisisiyi ati ni akoko iku wa.
Oluwa, Jesu Kristi, Iwo Eni ti o ri irewesi awon Kristiani, iwo ti o dana ife mimo Re sinu okan wa, nigba ti O tun apa ami ijiya Re se lara Fransiska mimo. L'oju rere aanu Re, ati nipa itoye ati ebe Re, fun wa ni oore-ofe lati ma ru agbelebu wa nigbagbogbo, ati lati so eso ironupiwada ti o ye.
Olorun, Olodumare ati ayeraye, saanu fun omo odo Re Papa mimo, ki O dari re gege bi aanu Re si ona igbala ainipekun, pe nipa oore-ofe Re ki o le se ohun ti o wu O, ki o si le se asepe ti awon iwa rere.
Olorun, iwo ti O fe darijini, ti O si fe igbala awon eniyan,awa nbebe lodo aanu Re, a sin be O nipa ebe Maria laelae Wundia, ati ti gbogbo awon eniyan mimo, ki Iwo ki o mu awon ara wa, egbe wa, ore wa, ati awon oloore wa oloogbe wa si ibi isimi alaafia ainipekun, nipase Jesu Kristi, Oluwa wa. Amin.
Parce Domine, } Dariji wa, Oluwa.
Parce Populo, tuo }x3 Dariji awon eniyan Re.
Ne in aeternum Irascaris nobis. } Ma se binu si wa titi lae.
Pie Jesu Domine Oluwa Jesu, oninu rere
Dona eis requiem,
Sempiternam Fun awon olodod oloogbe ni isimi ainipekun

Asiwaju: Jube, Domine Benedicere. Oluwa, fiyesi lati bukun fun wa.
Oludari yoo wipe:
Ki Oluwa Jesu Kristi ti a na ni pasan nitori wa, ti O ru agbelebu Re, ti a si kan mo agbelebu nitori wa bukun fun wa.No comments