Header Ads

Adura Aago Meta fun Aanu Olorun


Bere adura bayi:

Jesu, iwo ti ku nitooto, sugbon orison iye ti odo Re tu jade s’ori awon emi, aanu Re sit u jade s’ori gbogbo aye bi omi okun. A! Orisun iye, iwo Olorun ti aanu Re ko ni akawe, pa gbogbo aye mo, ki o si rojo aanu Re sori wa laaiseku si ibikan.

Lehin naa ka nigba meta:
A! Eje ati omi ti o tu jade lati inu okan Jesu, bi orison Aanu fun wa. Mo gbekele O.

ROSARIO TI AANU OLORUN
Adura ni idake je ninu okan

Baba wa ti m be L’Orun…
Mo ki O Maria…
Mo  gba Olorun Baba Olodumare gbo…

KIKA EKA MARAARUN TI ROSARIO
Kika eka-kookan bere, bayi:
Lori ileke nla, ka Adura yii:
Baba ayeraye mo fi ara ati eje, emi ati iwa-Olorun omo Re Ayanfe tooto, Oluwa wa Jesu Kristi, tore fun O, fun atunse awon ese wa ati ti gbogbo aye.
Lori awon ileke kekeke mewa, gba adura bayi:

Nitori ijiya onibanuje Re, Saanu fun wa ati fun gbogbo aye
Ni ipari gbigba awon adura eka Rosario mararun gba adura yii nigba meta:

Olorun Mimo
Eni Mimo, alagbara,
Eni-aiku Mimo
Saanu fun wa ati fun gbogbo aye
(Nigba meta).

AWON ADURA MIRAN FUN AANU OLORUN
Lehin Rosario kika, awon adura ipari meji, eyi ti a yo ninu ninu awon akosile ti Sisita (Siora) Faustina ni a o ka tele.

E JE KI A GBADURA
Olorun Ayeraye, Aanu ailopi wa ni ikawo Re aanu ko si n tan ninu isura oore Re, fi oju rere wo waa, ki o si jeki aanu Re le maa pos ii fun wa, ti yoo fi je pe, a ko ni so ireti nu tabi ki a ni irewesi okan, ni akoko isoro, bikose pe, ki a fi igbekele nla fi ara wa le ife Mimo Re lowo, eyi ti I se ife ati Aanu, fun ra re. Amin.

ADURA FUN AANU OLORUN
Olorun, Alaanu julo, Oloore ti ko lopin, gbogbo n ki gbe pe O si l’ojo oni, lati inu ogbun aye osi yi fun aanu ati oju rere. Olorun wa, igbe oro nla lati inu okan t’o kun fun osi ati ibanuje kikoro, l’o n tie nu omo-eda jade si O fun aanu. Olorun Alaanu, mase ko adura awon atipo-eni asati, inu aye yii. Olorun wa iwo ti aanu Re ga agbara oye wa lo, ti gbogbo ibanuje ati osi wa han si O kedere lati oke de isale, O si mo pe, ipa wa ko ka a lati goke wa si odo Re! Awa be O, fun wa ni oore-ofe Re, ki O si je ki aanu Re maa po sii lori wa, ki si le ma a fi tinutinu se ife Mimo Re, ni gbogbo ojo-aye wa ati ni akoko iku wa.
Je ki agbara aanu ailopin Re da-aabo bow a kuro ninu awon ohun idena ti awon ota n lo lati di igbala wa l’owo, ki awa omo re le ni igboya lati duro de wiwa Re ni ojo ikehin, eyi ti o je mimo fun iwo nikan soso.
Laika ipo osi ati ibanuje ti a wa si, a ni ireti lati ri ohun gbogbo ti Jesu se ileri fun wa gba, nitori pe Jesu ni ireti wa, nipa okan-Aanu Re gege bi enu-ona nla ti awa o gba de orun rere.
Adura ni idake je ninu okan fun awon edun okan wa.

ADURA EBE ATI IKESI AANU OLORUN
Olorun, Saanu fun wa.
Kristi, Saanu fun wa.
Oluwa, Saanu fun wa.
Kristi gbo ti wa.
Kristi fi oju-rere gbo tiwa.
Olorun, Baba orun…………………………..Saanu fun wa
Olorun Omo, Olurapada aye…………………Saanu fun wa
Olorun Emi-Mimo……………………….Saanu fun wa
Eni-Meta-Mimo ti I se Olorun kan………Saanu fun wa
Aanu Olorun, Iwo ase-ti o ga julo ninu iwa-ailopiin Eleda……………….Awa gbekele O.
Aanu Olorun, ise pipe ti Olurapada……………… ………………………..Awa gbekele O.
Aanu Olorun, ife ti ko l’opin ti Olusoni-di-Mimo…………………………. Awa gbekele O.
Aanu olorun, Ohun-ijinle ti Metalokan –Mimo ti o ga ju oye wa lo…….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o n fi agbara ti o tobi julo ti Olorun Oga-ogo han………. Awa gbekele O.
Aanu olorun ti a fihan ninu iseda awon Emi-Orun……………………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun ti o mu wa wa laaye lati inu ohun ti ko si…………………… Awa gbekele O.
Aanu olorun ti o ko gbogbo aye mora……………………………………...Awa gbekele O
Aanu olorun, iwo ti o fi iye-aiku ji-nki wa……………………………..… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o da aabo bow a kuro ninu awon ijiya ti o to si wa……… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o n yow a kuro ninu osi ti ese…………………………… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o se wa ni eni-yiye ninu Oro ti a so di Ara……………… Awa gbekele O
Aanu olorun, t’ o n san jade lati inu ogbe Kristi…………………………. Awa gbekele O.
Aanu olorun, t’ o n tu jade lati inu Okan-Mimo-Julo ti Jesu……………. Awa gbekele O.
Aanu olorun, t’o n fi Maria Wundia Alabunkun Julo fun wa ni Iya Aanu.. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti a fihan ninu ifihan awon-ohun ijinle ti Olorun………… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti a fihan ninu idasile Ijo agbaye……………………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o wa ninu idasile awon Sakaramenti Mimo………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti a fi fun gbogbo eniyan ninu awon Sakaramenti ti Ibatisi ati Ironupiwada
Aanu olorun, ti a fi fun wa ninu awon Sakaramenti ti ori pepe-Ebo Mimo ati ti Oye -Alufa
Aanu olorun, ti a fihan wa ninu iyipada awon elese…………………. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti a fihan ninu isodi-mimo awon Olododo…………….. Awa gbekele O
Aanu olorun, ti a muse nipa siso awon oniwa-mimo di pip………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, Orisun ilera fun awon alaisa ati awon ti iya nje………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, itunu fun awon ti okan won n je irora…………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ireti fun awon emi ti ainireti n yo l’en…………… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ti o n tele gbogbo eniyan nigba-gbogbo ati nibi gbogbo.. Awa gbekele O.
anu olorun, ti o n fi wa l’okan bale lati ri awon oore-ofe gba…..…… Awa gbekele O.
Aanu olorun, alaafia awon ti o n ku lo……………………………. Awa gbekele O.
Aanu olorun, itura ati itunu fun awon emi t’owa ni bi ina-iwenumo…… Awa gbekele O.
Aanu olorun, ayo atorun wa fun awon eni-ibukun……………………….. Awa gbekele O.
Aanu olorun, ade gbogbo eniyan-mimo………………………………… Awa gbekele O.
Aanu olorun,orison awon ise-iyanu ti ko l’opin………………………… Awa gbekele O.
Odo-Agutan  Olorun, iwo eniti o fi aanu Re ti o tobi julo han wa nipa irapada aye l’ori agbelebu…………Da wa si Oluwa.
Aanu olorun, Odo-Aguntan Olorun, Iwo Eni ti o n fi tanutanu fi ara Re rubo fun wa ninu…………Fi oju-rere gbo ti wa, Oluwa.
Odo-Aguntan Olorun, Iwo Eni ti o ko ese aye lo nipa Aanu Re ti ko lopin,………..Saanu fun wa,
Oluwa saanu fun wa.
Kristi saanu fun wa
Oluwa saanu fun wa,
Asaaju: Ife ati aanu Oluwa wa l’ori gbogbo ise Re
Idahun: Emi yoo korin aanu Oluwa titi lae.

Olorun, iwo Eni ti Aanu Re ko l’opin, ti isura ibanikedun re ko si tan, fi oju rere wow a, ki o si je ki Aanu Re maa pos ii l’ori wa, ti yoo fi je pe, ainireti ko ni bori wa, bi o ti wu ki isoro wa tobi to, bikose pe, ki a fi igbekele fi ara wa si abe ife mimo Re ti I se aanu funra Re. Nipase Jesu Kristi, Oluwa wa, Oba Aanu, Eni ti o n Saanu fun wa pelu Re ati Emi-Mimo, lae ati laelae. Amin.

No comments